We Will Miss You...............!!
Bi iku ba n gbowo a ba fun (×2),
Nitori Mama wa Oluyemi,
Keere o, o da arinako, o doju ala.
Bo ba se pe iku n gbo owo,
Gbogbo wa pata la o ba ti para po gbowo fun iku,
O da mi loju pe egbeegbeerun millions of Naira and pounds ni iku o ba ko rele oooo.
Bo ba wa se pe Iku n gba aso ni,
Dajudaju, iku o ba woso titi, iku iba tun mu ta.
Bo ba wa se pe iku n gba agutan bolojo nko o,
Mo ni iku o ba jeran titi, gbogbo eyin iku o ba re danu.
A mo o, iku o gbowo o, be ni o gba aso, bee ni o gba agutan bolojo,
Bi olojo ba ti de, iku a wole were.
Se aisan lo se wo, ko seni to le ri tolojo se.
Mo wo ile aye titi
Aye sa mala mala,
Ani mo boju w'orun,
Okunkun lo su bo le.
Mo sa ka titi
Bo ya mo le mo ibi taye ndori ko,
E ba bi mi lere naa pe, kini mo n wa ka oooo,
Se bi iku Oluyemi lo je n ma wa 'hun ti o sonu ka,
Ti gbogbo aye fi n se mi ni kayeefi.
Gbogbo wa pata pata la je gbese iku,
Ko seni to le ju si ile aye.
Tori, eni a ba ti bi ninu eniyan nko
O di danda, ko pada se' rupe.
Adura ni ka ma gba pe,
Ka gbo, ka to,
Ka fewu pari, ka ferigi jobi.
Titi a o fi pade lese Alawurabi,
Maami, Victoria Oluyemi,
Gbogbo wa pata pata lo n se lede leyin e.
Omo won nile Ajani,
Ajani Omo Karounwi,
Karounwi, omo agbode yinbo ode.
Omo Morenike Asabi to do logbe lojo to pe,
Asaabi, sabi agbon.
Sun re o, sun re , sun re.........!!!
A o pade eeeee lese JESU (song)
Nibi ti i a ko ni y'arawa,
A o ri ra wa,
A o yo mo ra wa,
Jesu ni o se alaga...........
Adieu ! Adieu !! Adieu !!!