Tribute by Queen Alovera Debie Oyin ti si lo ninu afara,afomo ti si kuro lo rin ope,eja la ti lo lomi,kiniun ololaju ti lo ni aginju,oguna ti re ludo,erin subu koledide,eni ba m'agbe ko se idaro aro,eni ba mo aluko ko se Idaro osu,eni ba mo lekeleke ko se idaro sese efun,aye eba wa se idaro eni re to lo, iku pa abiri,abiri tiku,iku pa abiri,abi ri rorun alekeji,Iku iba gbowo gbogbo wa laba fun lowo,iku iba gberan ,a ba ra agbo fun,a mo! Oma se oooo,iku o gba nkankan,afi dandan lai,omu eni ire lo,adejire omo oluwasegun oko tosin baba iyimide,jarule,ki olorun mu erupe ibi kuro loju e,ki o sun si aye okan olodumare,sunre ooooo.